28 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀,+29 tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+
43 Nígbà tó sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbóhùn sókè, ó sọ pé: “Lásárù, jáde wá!”+44 Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀. Jésù sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tú u, kí ẹ jẹ́ kó máa lọ.”