-
Jóòbù 1:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun,+ ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,+ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. 11 Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.” 12 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Gbogbo ohun tó ní wà ní ọwọ́ rẹ.* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ọkùnrin náà fúnra rẹ̀!” Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà.+
-
-
Sáàmù 38:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nítorí àwọn ọfà rẹ ti gún mi wọnú,
Ọwọ́ rẹ sì rìn mí mọ́lẹ̀.+
-