4 Nígbà náà, ọ̀kan lára ìyàwó àwọn ọmọ wòlíì+ sunkún lọ bá Èlíṣà, ó ní: “Ìránṣẹ́ rẹ, ọkọ mi, ti kú, o sì mọ̀ pé gbogbo ọjọ́ ayé ìránṣẹ́ rẹ ni ó fi bẹ̀rù Jèhófà.+ Àmọ́ ní báyìí, ẹni tí a jẹ ní gbèsè ti wá láti kó àwọn ọmọ mi méjèèjì kó lè fi wọ́n ṣe ẹrú.”