13 Bí ọ̀nà àwọn òmùgọ̀ ṣe rí nìyí+
Àti ti àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn, tí inú wọn ń dùn sí ọ̀rọ̀ asán tí wọ́n ń sọ. (Sélà)
14 A ti yàn wọ́n bí àgùntàn láti lọ sí Isà Òkú.
Ikú yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn;
Àwọn adúróṣinṣin yóò ṣàkóso wọn+ ní òwúrọ̀.
Wọ́n á pa rẹ́, tí a ò ní rí ipa wọn mọ́;+
Isà Òkú+ ló máa di ilé wọn dípò ààfin.+