12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ṣe búburú ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, kó sì pẹ́ láyé, síbẹ̀ mo mọ̀ pé ó máa dára fún àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 13 Àmọ́ kò ní dára fún ẹni burúkú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò lè mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ tó dà bí òjìji gùn,+ nítorí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.