Oníwàásù 8:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Mo wá wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì rí i pé aráyé kò lè lóye ohun tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.*+ Bó ti wù kí aráyé sapá tó, kò lè yé wọn. Kódà, tí wọ́n bá sọ pé ọgbọ́n àwọn gbé e láti mọ̀ ọ́n, wọn ò lè lóye rẹ̀ ní ti gidi.+ 1 Kọ́ríńtì 2:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí* tó mọ ọgbọ́n yìí,+ torí ká ní wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn ì bá má pa Olúwa ológo.* 1 Kọ́ríńtì 2:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Nítorí ta ló lè mọ ohun tí ẹnì kan ń rò àfi* onítọ̀hún? Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ẹni tó mọ àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, àfi ẹ̀mí Ọlọ́run.
17 Mo wá wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì rí i pé aráyé kò lè lóye ohun tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.*+ Bó ti wù kí aráyé sapá tó, kò lè yé wọn. Kódà, tí wọ́n bá sọ pé ọgbọ́n àwọn gbé e láti mọ̀ ọ́n, wọn ò lè lóye rẹ̀ ní ti gidi.+
8 Kò sí ìkankan nínú àwọn alákòóso ètò àwọn nǹkan yìí* tó mọ ọgbọ́n yìí,+ torí ká ní wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn ì bá má pa Olúwa ológo.*
11 Nítorí ta ló lè mọ ohun tí ẹnì kan ń rò àfi* onítọ̀hún? Bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ẹni tó mọ àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, àfi ẹ̀mí Ọlọ́run.