-
Jóòbù 20:26-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Òkùnkùn biribiri ń dúró de àwọn ìṣúra rẹ̀;
Iná tí ẹnì kankan ò fẹ́ atẹ́gùn sí máa jẹ ẹ́ run;
Àjálù máa bá ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú àgọ́ rẹ̀.
27 Ọ̀run máa tú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ síta;
Ayé máa dìde sí i.
28 Àkúnya omi máa gbé ilé rẹ̀ lọ;
Ọ̀gbàrá máa pọ̀ gan-an ní ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.*
29 Èyí ni ìpín ẹni burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,
Ogún tí Ọlọ́run ti pín fún un.”
-