-
Ẹ́kísódù 9:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Mósè wá na ọ̀pá rẹ̀ sí ọ̀run, Jèhófà sì mú kí ààrá sán, yìnyín bọ́, iná* sọ̀ kalẹ̀, Jèhófà sì ń mú kí òjò yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì.
-
-
1 Sámúẹ́lì 12:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Òní kọ́ ni ọjọ́ ìkórè àlìkámà* ni? Màá ké pe Jèhófà kí ó sán ààrá kí ó sì rọ òjò; kí ẹ wá mọ̀, kí ẹ sì lóye pé ohun búburú ni ẹ ṣe lójú Jèhófà nígbà tí ẹ ní kí ó fún yín ní ọba.”+
18 Ni Sámúẹ́lì bá ké pe Jèhófà, Jèhófà wá sán ààrá, ó sì rọ òjò ní ọjọ́ yẹn, tí gbogbo àwọn èèyàn náà fi bẹ̀rù Jèhófà àti Sámúẹ́lì gidigidi.
-