-
Jẹ́nẹ́sísì 18:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ǹjẹ́ a rí ohun tó pọ̀ jù fún Jèhófà+ láti ṣe? Màá pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní àkókò yìí lọ́dún tó ń bọ̀, Sérà yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”
-
-
Sáàmù 135:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́+
Ní ọ̀run àti ní ayé, nínú òkun àti nínú gbogbo ibú omi.
-
-
Àìsáyà 43:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Tí mo bá ń ṣe nǹkan kan, ta ló lè dá mi dúró?”+
-
-
Jeremáyà 32:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó! Agbára ńlá rẹ+ àti apá rẹ tí o nà jáde lo fi dá ọ̀run àti ayé. Kò sí ohun tó ṣòroó ṣe fún ọ,
-
-
Máàkù 10:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Jésù wò wọ́n tààrà, ó sì sọ pé: “Lójú èèyàn, kò ṣeé ṣe, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, torí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+
-
-
Lúùkù 18:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún èèyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+
-