- 
	                        
            
            Sáàmù 108:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        2 Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+ Màá jí ní kùtùkùtù. 3 Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn, Màá sì fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. 4 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+ Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà. 5 Gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run; Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+ 
 
-