-
2 Àwọn Ọba 9:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Jéhù mú ọfà,* ó sì ta á lu Jèhórámù ní àárín méjì ẹ̀yìn rẹ̀, ọfà náà jáde ní ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú sínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
-
-
Lúùkù 11:49-51Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
49 Ìdí nìyẹn tí ọgbọ́n Ọlọ́run náà fi sọ pé: ‘Màá rán àwọn wòlíì àti àwọn àpọ́sítélì sí wọn, wọ́n máa pa àwọn kan, wọ́n sì máa ṣe inúnibíni sí àwọn kan lára wọn, 50 ká lè di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn wòlíì tí wọ́n ta sílẹ̀ látìgbà ìpìlẹ̀ ayé ru* ìran yìí,+ 51 látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ títí dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà, tí wọ́n pa láàárín pẹpẹ àti ilé.’*+ Àní, mò ń sọ fún yín, a máa di ẹ̀bi rẹ̀ ru* ìran yìí.
-