- 
	                        
            
            Diutarónómì 1:42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        42 Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Sọ fún wọn pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ gòkè lọ jà, torí mi ò ní bá yín lọ.+ Tí ẹ bá lọ, àwọn ọ̀tá yín máa ṣẹ́gun yín.”’ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Diutarónómì 20:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        4 torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín lọ kó lè jà fún yín láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín, kó sì gbà yín là.’+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Jóṣúà 7:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        12 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n á yí pa dà lẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì sá lọ, torí wọ́n ti di ohun tí a máa pa run. Mi ò ní wà pẹ̀lú yín mọ́, àfi tí ẹ bá run ohun tí a máa pa run tó wà láàárín yín.+ 
 
-