10 Lẹ́yìn náà, ó fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ńtì* wúrà àti òróró básámù+ tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.+ Kò tún sẹ́ni tó kó irú òróró básámù tó pọ̀ wọlé bí èyí tí ọbabìnrin Ṣébà kó wá fún Ọba Sólómọ́nì.
23 Ọ̀pọ̀ èèyàn mú ẹ̀bùn wá fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì mú àwọn ohun iyebíye wá fún Hẹsikáyà ọba Júdà,+ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń bọ̀wọ̀ fún un gidigidi lẹ́yìn náà.