2 Sámúẹ́lì 23:3, 4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀;Àpáta Ísírẹ́lì+ sọ fún mi pé: ‘Nígbà tí ẹni tó ń ṣàkóso aráyé bá jẹ́ olódodo,+Tó ń fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣàkóso,+ 4 Á dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn yọ,+Tí ojúmọ́ mọ́, tí kò sí ìkùukùu. Bí ìmọ́lẹ̀ tó yọ lẹ́yìn tí òjò dá,Tó ń mú kí ewéko yọ láti inú ilẹ̀.’+ Òwe 16:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Ẹni tó bá rí ojú rere ọba, ayé onítọ̀hún á ládùn;Ojú rere rẹ̀ dà bíi ṣíṣú òjò ìgbà ìrúwé.+ Òwe 19:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Ìrunú ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn,+Àmọ́ ojú rere rẹ̀ dà bí ìrì lára ewéko.
3 Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀;Àpáta Ísírẹ́lì+ sọ fún mi pé: ‘Nígbà tí ẹni tó ń ṣàkóso aráyé bá jẹ́ olódodo,+Tó ń fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣàkóso,+ 4 Á dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn yọ,+Tí ojúmọ́ mọ́, tí kò sí ìkùukùu. Bí ìmọ́lẹ̀ tó yọ lẹ́yìn tí òjò dá,Tó ń mú kí ewéko yọ láti inú ilẹ̀.’+