21 Ní ọ̀sán, Jèhófà máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* kó lè máa darí wọn lójú ọ̀nà,+ àmọ́ ní òru, ó máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n iná* kó lè fún wọn ní ìmọ́lẹ̀, kí wọ́n lè máa bá ìrìn àjò wọn lọ tọ̀sántòru.+
20 Ó wà láàárín àwùjọ àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ó mú kí òkùnkùn ṣú lápá kan. Àmọ́ lápá kejì, ó mú kí ìmọ́lẹ̀ wà ní òru yẹn.+ Torí náà, àwùjọ kìíní ò dé ọ̀dọ̀ àwùjọ kejì ní gbogbo òru yẹn.