-
Nọ́ńbà 14:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn pé: “Ó sàn ká ti kú sí ilẹ̀ Íjíbítì tàbí ká tiẹ̀ ti kú sínú aginjù yìí! 3 Kí ló dé tí Jèhófà fẹ́ mú wa wá sí ilẹ̀ yìí kí wọ́n lè fi idà+ pa wá? Wọ́n á kó+ àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní dáa ká pa dà sí Íjíbítì?”+ 4 Wọ́n tiẹ̀ ń sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká yan ẹnì kan ṣe olórí wa, ká sì pa dà sí Íjíbítì!”+
-
-
1 Kọ́ríńtì 10:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Bákan náà, kí a má ṣe ìṣekúṣe,* bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe ìṣekúṣe,* tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) lára wọn fi kú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+ 9 Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà* wò,+ bí àwọn kan nínú wọn ṣe dán an wò, tí ejò sì ṣán wọn pa.+ 10 Bákan náà, kí ẹ má ṣe máa kùn, bí àwọn kan nínú wọn ṣe kùn,+ tí apanirun sì pa wọ́n.+
-