26 báyìí la ṣe máa gba gbogbo Ísírẹ́lì+ là. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Olùdáǹdè máa wá láti Síónì,+ á sì yí àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù. 27 Èyí sì ni májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”+