- 
	                        
            
            2 Sámúẹ́lì 19:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        34 Àmọ́ Básíláì sọ fún ọba pé: “Ọjọ́* mélòó ló kù tí màá lò láyé tí màá fi bá ọba lọ sí Jerúsálẹ́mù? 35 Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni mí lónìí.+ Ṣé mo ṣì lè fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú? Ṣé èmi ìránṣẹ́ rẹ lè mọ adùn ohun tí mò ń jẹ àti ohun tí mò ń mu? Ṣé mo ṣì lè gbọ́ ohùn àwọn akọrin + lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Ṣé ó wá yẹ kí ìránṣẹ́ rẹ tún jẹ́ ẹrù fún olúwa mi ọba? 
 
-