10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
7 Ó ń sọ̀rọ̀ tó dún ketekete pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, torí wákàtí tó máa ṣèdájọ́ ti dé,+ torí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun+ àti àwọn ìsun* omi.”