-
Ìṣe 2:25-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Dáfídì sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Mo gbé Jèhófà* síwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, kí mìmì kan má bàa mì mí. 26 Nítorí èyí, ara mi yá gágá, ahọ́n mi sì ń yọ̀ gidigidi. Màá* sì máa fi ìrètí gbé ayé; 27 torí o ò ní fi mí* sílẹ̀ nínú Isà Òkú,* bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.+ 28 O ti jẹ́ kí n mọ ọ̀nà ìyè; wàá mú kí ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’+
-