11 Bàbá mi, wò ó, etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá rèé lọ́wọ́ mi; nígbà tí mo gé etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ tí kò lápá, mi ò pa ọ́. Ṣé ìwọ náà rí i, ṣé o sì ti wá mọ̀ báyìí pé mi ò gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá tàbí kí n dìtẹ̀ sí ọ? Mi ò ṣẹ̀ ọ́,+ àmọ́ ńṣe ni ò ń dọdẹ mi kiri láti gba ẹ̀mí mi.+