-
Ìṣe 1:16-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, ó pọn dandan kí ìwé mímọ́ ṣẹ, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ gba ẹnu Dáfídì sọ nípa Júdásì,+ ẹni tó ṣamọ̀nà àwọn tó wá mú Jésù.+ 17 Nítorí a ti kà á mọ́ wa,+ ó sì ní ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí. 18 (Ọkùnrin yìí fi owó iṣẹ́ ibi+ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan, àmọ́, ó fi orí sọlẹ̀, ikùn rẹ̀ bẹ́,* gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú síta.+ 19 Gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì pe ilẹ̀ náà ní Ákélídámà ní èdè wọn, ìyẹn, “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) 20 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Sáàmù pé, ‘Kí ibi tó ń gbé di ahoro, kí ó má ṣe sí ẹnì kankan tí á máa gbé inú rẹ̀’+ àti pé, ‘Kí ẹlòmíì gba iṣẹ́ àbójútó rẹ̀.’+
-