- 
	                        
            
            Jeremáyà 25:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        31 ‘Ariwo kan á dún títí dé ìkángun ayé, Nítorí Jèhófà ní ẹjọ́ kan pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè. Òun fúnra rẹ̀ á ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn èèyàn.*+ Á sì fi idà pa àwọn ẹni burúkú,’ ni Jèhófà wí. 32 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: ‘Wò ó! Àjálù kan ń ṣẹlẹ̀ kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+ A ó sì tú ìjì líle jáde láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+ 33 “‘Àwọn tí Jèhófà máa pa ní ọjọ́ yẹn máa pọ̀ láti ìkángun kan ayé títí dé ìkángun kejì. A ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, a ò ní kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní sin wọ́n. Wọ́n á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.’ 
 
-