-
1 Sámúẹ́lì 23:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dé ẹ̀gbẹ́ kan òkè náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkè náà. Dáfídì ṣe kánkán+ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, àmọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti gbá wọn mú.+ 27 Ṣùgbọ́n òjíṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Tètè máa bọ̀, nítorí àwọn Filísínì ti wá kó ẹrù ní ilẹ̀ wa!” 28 Ni Sọ́ọ̀lù ò bá lépa Dáfídì mọ́,+ ó sì lọ gbéjà ko àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Ìpínyà.
-
-
2 Sámúẹ́lì 17:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Lẹ́yìn tí àwọn ọkùnrin náà ti lọ, wọ́n jáde nínú kànga náà, wọ́n sì lọ sọ fún Ọba Dáfídì. Wọ́n sọ fún un pé: “Ẹ gbéra, kí ẹ sì sọdá odò kíákíá, torí ohun tí Áhítófẹ́lì ti dámọ̀ràn láti ṣe sí yín nìyí.”+ 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbéra, wọ́n sì sọdá Jọ́dánì. Nígbà tí ilẹ̀ máa fi mọ́, kò sẹ́ni tó ṣẹ́ kù tí kò tíì sọdá Jọ́dánì.
-