ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 7:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Lójú ẹsẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ gẹ́lẹ́. Ó na ọ̀pá náà sókè, ó sì fi lu omi odò Náílì níṣojú Fáráò àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, gbogbo omi odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.+

  • Ẹ́kísódù 8:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Áárónì wá na ọwọ́ rẹ̀ sórí àwọn omi Íjíbítì, àwọn àkèré sì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde, wọ́n sì bo ilẹ̀ Íjíbítì.

  • Ẹ́kísódù 8:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Áárónì na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì fi lu erùpẹ̀, àwọn kòkòrò náà wá bo èèyàn àti ẹranko. Gbogbo erùpẹ̀ di kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.+

  • Ẹ́kísódù 9:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kejì, gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi sì bẹ̀rẹ̀ sí í kú,+ àmọ́ ìkankan nínú ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kú.

  • Ẹ́kísódù 9:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Torí náà, wọ́n bu eérú níbi ààrò, wọ́n sì dúró níwájú Fáráò, Mósè wá fọ́n ọn sínú afẹ́fẹ́, ó sì di eéwo tó ń ṣọyún lára èèyàn àti ẹranko.

  • Ẹ́kísódù 9:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Mósè wá na ọ̀pá rẹ̀ sí ọ̀run, Jèhófà sì mú kí ààrá sán, yìnyín bọ́, iná* sọ̀ kalẹ̀, Jèhófà sì ń mú kí òjò yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀ Íjíbítì.

  • Ẹ́kísódù 10:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí ilẹ̀ Íjíbítì kí àwọn eéṣú lè jáde, kí wọ́n bo ilẹ̀ Íjíbítì, kí wọ́n sì run gbogbo ewéko ilẹ̀ náà tán, gbogbo ohun tí òjò yìnyín ṣẹ́ kù.”

  • Ẹ́kísódù 10:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sí ọ̀run, kí òkùnkùn lè bo ilẹ̀ Íjíbítì, òkùnkùn tó máa ṣú biribiri débi pé á fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣeé fọwọ́ bà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́