2 ní ọdún kìíní ìjọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi òye mọ̀ látinú ìwé, iye ọdún tí Jèhófà sọ fún wòlíì Jeremáyà pé Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro,+ ìyẹn àádọ́rin (70) ọdún.+ 3 Mo wá yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, mo bẹ̀ ẹ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà sí i, pẹ̀lú ààwẹ̀,+ aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.