26 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dé ẹ̀gbẹ́ kan òkè náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkè náà. Dáfídì ṣe kánkán+ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, àmọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti gbá wọn mú.+
29 Tí ẹnì kan bá dìde láti lépa rẹ, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ, Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi ẹ̀mí* olúwa mi pa mọ́ sínú àpò ìwàláàyè lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní ti ẹ̀mí* àwọn ọ̀tá rẹ, òun yóò ta á jáde bí ìgbà tí èèyàn fi kànnàkànnà ta òkúta.*