Sáàmù 92:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Láti máa kéde pé adúróṣinṣin ni Jèhófà. Òun ni Àpáta+ mi, ẹni tí kò sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. Sáàmù 119:68 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 68 Ẹni rere ni ọ́,+ àwọn iṣẹ́ rẹ sì dára. Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.+ Sáàmù 145:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá,+Àánú rẹ̀ sì wà lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Ìṣe 14:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+
17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+