-
Hébérù 10:5-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Torí náà, nígbà tó wá sí ayé, ó sọ pé: “‘Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tí o fẹ́, àmọ́ ìwọ pèsè ara kan fún mi. 6 O ò fọwọ́ sí àwọn odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.’+ 7 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: ‘Wò ó! Mo ti dé (a ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé*) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’”+ 8 Lẹ́yìn tó kọ́kọ́ sọ pé: “O ò fẹ́ àwọn ẹbọ, ọrẹ, odindi ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, o ò sì fọwọ́ sí i”—àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú, bí Òfin ṣe sọ— 9 ó wá sọ pé: “Wò ó! Mo ti dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”+ Ó fi òpin sí èyí àkọ́kọ́ kó lè fìdí ìkejì múlẹ̀.
-