60 Wọ́n súre fún Rèbékà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Arábìnrin wa, wàá di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,* àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn tó kórìíra wọn lọ́wọ́ wọn.”+
3 Kí ẹwà yín má ṣe jẹ́ ti òde ara, bí irun dídì, wíwọ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà+ tàbí wíwọ àwọn aṣọ olówó ńlá, 4 àmọ́ kó jẹ́ ti ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn, kí ẹ fi ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù ṣe ọ̀ṣọ́ tí kò lè bà jẹ́,+ èyí tó níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run.