-
Diutarónómì 28:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Àmọ́ tí o ò bá pa gbogbo àṣẹ àti òfin Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, láti fi hàn pé ò ń fetí sí ohùn rẹ̀, gbogbo ègún yìí máa wá sórí rẹ, ó sì máa bá ọ:+
-
-
Jóṣúà 7:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá mú Ákánì+ ọmọ Síírà, fàdákà náà, ẹ̀wù oyè náà àti wúrà gbọọrọ náà,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, akọ màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Àfonífojì* Ákórì.+ 25 Jóṣúà sọ pé: “Kí ló dé tí o fa àjálù* bá wa?+ Jèhófà máa mú àjálù bá ọ lónìí.” Ni gbogbo Ísírẹ́lì bá sọ ọ́ lókùúta,+ lẹ́yìn náà, wọ́n dáná sun wọ́n.+ Bí wọ́n ṣe sọ gbogbo wọn lókùúta nìyẹn.
-
-
Ẹ́sítà 9:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Hámánì+ ọmọ Hamédátà, ọmọ Ágágì,+ ọ̀tá gbogbo àwọn Júù ti gbèrò láti pa àwọn Júù run,+ ó ti ṣẹ́ Púrì,+ ìyẹn Kèké, láti kó ìpayà bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run. 25 Àmọ́ nígbà tí Ẹ́sítà wá síwájú ọba, ọba pa àṣẹ kan tí wọ́n kọ sílẹ̀ pé:+ “Kí èrò ibi tí ó gbà sí àwọn Júù+ pa dà sórí rẹ̀”; wọ́n sì gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi.+
-