-
Jẹ́nẹ́sísì 39:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Lẹ́yìn náà, ojú ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù kò kúrò lára rẹ̀, ó sì ń sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” 8 Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà, ó sì sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá mi kì í yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò nínú ilé, ó sì ti fa gbogbo ohun tó ní lé mi lọ́wọ́.
-
-
Diutarónómì 13:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Tí arákùnrin rẹ, ọmọ ìyá rẹ tàbí ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ tàbí ìyàwó rẹ tí o fẹ́ràn tàbí ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́,* bá gbìyànjú láti tàn ọ́ ní ìkọ̀kọ̀ pé, ‘Jẹ́ ká lọ sin àwọn ọlọ́run míì,’+ àwọn ọlọ́run tí ìwọ àtàwọn baba ńlá rẹ kò mọ̀, 7 lára àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká, ì báà jẹ́ nítòsí tàbí àwọn tó jìnnà sí yín, láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ náà dé ìpẹ̀kun rẹ̀ kejì, 8 o ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn tàbí kí o fetí sí i,+ o ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀ tàbí kí o yọ́nú sí i, o ò sì gbọ́dọ̀ dáàbò bò ó;
-