8 “Tí ẹnì kan bá pè ọ́ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe jókòó síbi tó lọ́lá jù.+ Ó ṣeé ṣe kó ti pe ẹnì kan tí wọ́n kà sí pàtàkì jù ọ́ lọ. 9 Ẹni tó pe ẹ̀yin méjèèjì á wá sọ fún ọ pé, ‘Dìde fún ọkùnrin yìí.’ O máa wá fi ìtìjú dìde lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ.