Sáàmù 26:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 26 Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, nítorí mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi;+Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé láìmikàn.+ Òwe 13:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Òdodo ń dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+Àmọ́ ìwà burúkú máa ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.