5 Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tó bí Ísákì ọmọ rẹ̀. 6 Sérà wá sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.”*7 Ó fi kún un pé: “Ta ni ì bá sọ fún Ábúráhámù pé, ‘Ó dájú pé Sérà yóò di ìyá ọlọ́mọ’? Síbẹ̀ mo bímọ fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.”