34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo lẹ ṣe lè sọ àwọn ohun tó dáa nígbà tó jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín? Torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.+ 35 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀.+