16 Nítorí náà, ẹ máa jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ fún ara yín láìfi ohunkóhun pa mọ́, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, ká lè mú yín lára dá. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.*+
21 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà níwájú Ọlọ́run;+22 a sì ń rí ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà,+ torí à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tó dáa lójú rẹ̀.