37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+38 Èyí ni àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́. 39 Ìkejì tó dà bíi rẹ̀ nìyí: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’+40 Àṣẹ méjì yìí ni gbogbo Òfin àti àwọn Wòlíì rọ̀ mọ́.”+