-
Jẹ́nẹ́sísì 32:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Kí ẹ tún sọ pé, ‘Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’” Torí ó sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: ‘Tí mo bá kọ́kọ́ fi ẹ̀bùn ránṣẹ́,+ tí mo fi wá ojúure rẹ̀, tí mo bá wá rí òun fúnra rẹ̀, bóyá ó lè tẹ́wọ́ gbà mí.’
-
-
2 Sámúẹ́lì 16:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tí Dáfídì kọjá orí òkè+ náà díẹ̀, Síbà+ ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́,* igba (200) búrẹ́dì, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù àjàrà gbígbẹ, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn* àti ìṣà* wáìnì ńlá+ kan sì wà lórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.
-