-
Oníwàásù 9:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà. 15 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+
-
-
Jémíìsì 2:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Tí ẹnì kan bá wá sí ìpàdé yín, tó wọ àwọn òrùka wúrà sí ìka rẹ̀, tó sì wọ aṣọ tó dáa gan-an, àmọ́ tí tálákà kan tó wọ aṣọ tó dọ̀tí náà wọlé wá, 3 ṣé ẹ máa fi ojúure wo ẹni tó wọ aṣọ tó dáa gan-an, tí ẹ máa sọ pé, “Jókòó síbi tó dáa yìí,” tí ẹ sì máa wá sọ fún tálákà náà pé, “Ìwọ wà lórí ìdúró” tàbí, “Jókòó síbẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi”?+
-