-
Jẹ́nẹ́sísì 9:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nóà wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó sì gbin ọgbà àjàrà kan. 21 Nígbà tó mu lára wáìnì rẹ̀, ọtí bẹ̀rẹ̀ sí í pa á, ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò nínú àgọ́ rẹ̀.
-
-
Òwe 23:29-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ta ló ni ìyà? Ta ló ni àìnírọ̀rùn?
Ta ló ni ìjà? Ta ló ni àròyé?
Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú tó ń ṣe bàìbàì?*
31 Má ṣe wo àwọ̀ pupa wáìnì
Bó ṣe ń ta wíríwírí nínú ife, tó sì ń lọ tìnrín,
32 Torí níkẹyìn, á buni ṣán bí ejò,
Á sì tu oró jáde bíi paramọ́lẹ̀.
34 Wàá dà bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí àárín òkun,
Bí ẹni tó dùbúlẹ̀ sí orí òpó ọkọ̀ òkun.
35 Wàá sọ pé: “Wọ́n lù mí, àmọ́ mi ò mọ̀ ọ́n lára.*
Wọ́n nà mí, àmọ́ mi ò mọ̀.
Ìgbà wo ni màá jí?+
Ẹ fún mi lọ́tí sí i.”*
-