ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 15:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Sámúẹ́lì wá sọ pé: “Ṣé àwọn ẹbọ sísun àti ẹbọ+ máa ń múnú Jèhófà dùn tó kéèyàn ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ,+ fífi etí sílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá+ àgbò; 23 nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan náà ni ìṣọ̀tẹ̀+ àti iṣẹ́ wíwò+ jẹ́, ọ̀kan náà sì ni kíkọjá àyè jẹ́ pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ìbọ̀rìṣà.* Nítorí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,+ òun náà ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”+

  • Hósíà 6:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Nítorí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* ni inú mi dùn sí, kì í ṣe ẹbọ

      Àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò odindi ẹbọ sísun.+

  • Míkà 6:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,

      Sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró?+

      Ṣé màá fi àkọ́bí mi ọkùnrin rúbọ torí ọ̀tẹ̀ tí mo dì,

      Àbí màá fi èso ikùn mi rúbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ mi?*+

       8 Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.

      Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe?*

      Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,*+ kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin,*+

      Kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ+ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!+

  • Mátíù 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ṣùgbọ́n ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́,+ kì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́