14 Àmọ́ kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́,+ o sì mọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn 15 àti pé láti kékeré jòjòló + lo ti mọ ìwé mímọ́,+ èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+