-
Ìṣe 13:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àmọ́ Élímà oníṣẹ́ oṣó náà (torí bí wọ́n ṣe túmọ̀ orúkọ rẹ̀ nìyẹn) bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wọ́n, ó fẹ́ yí alákòóso ìbílẹ̀ náà kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. 9 Ni Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n tún ń pè ní Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, bá tẹjú mọ́ ọn, 10 ó sì sọ pé: “Ìwọ ọkùnrin tí oríṣiríṣi jìbìtì àti ìwà ibi kún ọwọ́ rẹ̀, ìwọ ọmọ Èṣù,+ ìwọ ọ̀tá gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo, ṣé o kò ní ṣíwọ́ yíyí àwọn ọ̀nà títọ́ Jèhófà* po ni?
-