5 Ẹ sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pátápátá, tó fi bá yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé: “Ọmọ mi, má fojú kéré ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà, má sì sọ̀rètí nù nígbà tó bá tọ́ ọ sọ́nà; 6 torí àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí, àní, gbogbo ẹni tó gbà bí ọmọ ló máa ń nà lẹ́gba.”+