16 torí gbogbo ohun tó wà nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú+ àti fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn—kò wá látọ̀dọ̀ Baba, àmọ́ ó wá látọ̀dọ̀ ayé. 17 Bákan náà, ayé ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.+