7 Síbẹ̀, àwọn ohun tó jẹ́ èrè fún mi ni mo ti kà sí àdánù nítorí Kristi.+ 8 Yàtọ̀ síyẹn, mo ti ka ohun gbogbo sí àdánù nítorí ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi ṣeyebíye ju ohun gbogbo lọ. Nítorí rẹ̀, mo ti gbé ohun gbogbo sọ nù, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi,