-
Lúùkù 14:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Tí ẹnì kan bá pè ọ́ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe jókòó* síbi tó lọ́lá jù.+ Ó ṣeé ṣe kó ti pe ẹnì kan tí wọ́n kà sí pàtàkì jù ọ́ lọ. 9 Ẹni tó pe ẹ̀yin méjèèjì á wá sọ fún ọ pé, ‘Dìde fún ọkùnrin yìí.’ O máa wá fi ìtìjú dìde lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ. 10 Àmọ́ tí wọ́n bá pè ọ́, lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù, kó lè jẹ́ pé tí ẹni tó pè ọ́ wá bá dé, ó máa sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, lọ síbi tó ga.’ Ìgbà yẹn lo máa wá gbayì níṣojú gbogbo àwọn tí ẹ jọ jẹ́ àlejò.+
-