-
2 Sámúẹ́lì 20:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Jóábù sọ fún Ámásà pé: “Arákùnrin mi, ṣé dáadáa lo wà?” Ni Jóábù bá fi ọwọ́ ọ̀tún di irùngbọ̀n Ámásà mú bíi pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 10 Ámásà kò fura sí idà ọwọ́ Jóábù; Jóábù fi idà náà gún un ní ikùn,+ ìfun rẹ̀ sì tú síta sórí ilẹ̀. Kò gún un lẹ́ẹ̀mejì, ìgbà kan péré ti tó láti pa á. Lẹ́yìn náà, Jóábù àti Ábíṣáì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lépa Ṣébà ọmọ Bíkíráì.
-