10 Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 11 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Kọ́bánì (ìyẹn, ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run) ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”’